AJIGBESE anu ni mi
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
AJIGBESE anu ni mi,
Mo ti ba majemu mi je;
Laifoya ninu pipe Re,
Mo gb’ ara at ore mi wa.
Verse 2
Eru ofin at’ Olorun
Ko ri ipa sa lodo mi;
Igboran Olugbala mi
Bo gbogbo ese mi mo ‘le.
Verse 3
Ise ti ore Re bere
Ni agbara Re yio pari;
Amin, beni ileri Re,
A ko si gbo p’ o saki ri.
Verse 4
Ko s’ ohun kan l’ aiye, l’ orun,
T’ isiyi, ab’ eyi ti mbo,
T’ o le mu ki ife Re ye,
Tabi k’ o ja mi l’ owo Re.
Verse 5
Oruko mi lo ko le pare
Kuro li atewo Re lai!
O wa li okan aiya Re,
Ore-ofe l’ o ko sibe.
Verse 6
Daju, emi yio wa titi,
A ti san owo ‘lele mi;
Awon t’ orun le ta mi yo
L’ ayo sugbon ki se l’ ebun.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.