Yoruba Baptist Hymns
B’ AYO aiye ti j’ asan to
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
B’ AYO aiye ti j’ asan to!
Didara won ko pe!
Ko s’ ayo ti ko l’ ororo,
Adun re je ‘dekun.
Verse 2
Gbogb’ ohun t’ o dara l’ aiye,
Li o nfi etan dan,
O ye k’ a fura nigb’ ayo,
Pe, ewu sunmo ni.
Verse 3
Ayo wa, at’ awon t’ a fe,
At’ awon ebi wa,
Nwon ko jek’ a le f’ okan wa
Gbogbo fun Olorun.
Verse 4
Ife si ohun ti aiye
Ti gba wa l’ okan tan,
O soro lati mu ‘tara
Wa kuro ninu re.
Verse 5
Olugbala, ki ewa Re
Je onje f’ okan mi;
K’ ore-ofe wi f’ okan mi,
K’ o ju aiye sile.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/b-ayo-aiye-ti-j-asan-to/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.