Yoruba Baptist Hymns
ILE ayo kan wa
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
ILE ayo kan wa
Ti o Jina,
Ti awon mimo wa;
Nwon nran b’ orun;
A! nwon nkorin didun,
Yiye l’ Olugbala wa,
Ki iyin Re ko ro,
Yin, yin lailai.
Verse 2
Wa s’ ile ayo na,
Wa, wa kalo;
E se nsiyemeji?
E se nduro?
A o wa l’ alafia,
Kuro l’ ese at’ aro,
A o ba O joba,
L’ ayo lailai.
Verse 3
Oju gbogbo won ndan
N’ ile ayo;
N’ ipamo Baba wa,
Ife ki ku.
Nje sure lo s’ ogo,
Gba ade at’ ijoba,
T’ o mo ju orun lo,
Joba titi.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/ile-ayo-kan-wa/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.