F’ AWON enia Re t’ o lo ‘smi
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
F’ AWON enia Re t’ o lo ‘smi
Awon ti o f’ igbagbo jewo Re,
Ki yin oruko Re, Olugbala,
Alleluya!
Verse 2
Iwo l’ apata won at’ odi won,
Iwo ni Balogun won l’ oju ‘ja
Iwo ni imole okunkun won,
Alleluya!
Verse 3
Jek’ awon omo-ogun Re l’ aiye,
Jagun nitoto b’ awon t’ igbani
Ki nwon le gba ade ogo bi won,
Alleluya!
Verse 4
Idapo ibukun wo l’ o to yi!
Awa nja nihin, awon nyo lohun;
Be Tire kanna l’ awa at’ awon.
Alleluya!
Verse 5
Gbat’ ija ba ngbona, ti ogun nle,
A dabi eni ngborin ayo won;
Igboiya a sid e, at’ agbra.
Alleluya!
Verse 6
Ojo nlo, orun wa fere won a,
Awon ajagun toto y’o simi;
Didun ni isimi Paradise,
Alleluya!
Verse 7
Lehin eyi ojo ayo kan mbo,
Awon mimo y’o dide n’nu ogo;
Oba ogo yio wa larin won,
Alleluya!
Verse 8
Lat’ opin ile, lat’ opin okun,
Ogunlogo nro wo ‘bode pearli
Nwon nyin Baba, Omo ati Emi.
Alleluya!
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.