WO Imole! larin okun aiye
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
WO Imole! larin okun aiye,
Ma sin mi lo.
Okunkun su, mo si jina s’ ile,
Ma sin mi lo.
To ‘sise mi: bi ona ti jin to,
Nki o bere; ‘sise kan to fun mi.
Verse 2
Nigbakan ri, emi ko be O pe
Ma sin mi lo;
Beni nko fe O; sugbon nigbayi
Ma sin mi lo;
Afe aiye ni mo ti nto lehin,
Sugbon Jesu, ma ranti igba ni.
Verse 3
Ipa Re l’o ti ndi mi mu, yio si
Ma sin mi lo;
Ninu ere ati yangi aiye,
Ma sin mi lo.
Titi em’ o fi ri awon wonni
Ti mo fe, ti nwon ti f’ aiye sile.
Verse 4
Ko to d’ igba na, lona aiye yi
T’ Iwo ti rin,
Ma sin mi lo Jesu Olugbala
S’ ile Baba;
Ki nle simi lehin ija aiye
Ninu imole ti ko nipekun.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.