WO t’ o nbebe f’ ota Re
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
WO t’ o nbebe f’ ota Re,
L’ or’ igi agbelebu;
Wipe “Fiji won Baba”,
Jesu sanu fun wa.
Verse 2
Jesu jo bebe fun wa,
Fun ese wa gbagbogbo;
A ko mo ohun t a nse
Jesu sanu fun wa.
Verse 3
Je k’ awa ti nwa anu,
Dabi Re l’ okan n’ iwa,
‘Gba t’ a ba se wa n’ ibi:
Jesu sanu fun wa.
Verse 4
Jesu ‘Wo t’ o gbo aro
Ole t’ o ku l’ egbe Re,
T’ O si mu d’ orun rere:
Jesu sanu fun wa.
Verse 5
Ninu ebi ese wa,
Je k’ a toro anu Re,
K’ a ma pe oruko Re,
Jesu sanu fun wa.
Verse 6
Ranti awa ti nrahun
T’ a now agbelebu Re;
F’ ireti mimo fun wa
Jesu sanu fun wa.
Verse 7
‘Wo t’ o fe l’afe dopin
Iya Re t’ o nkanu Re,
Ati ore Re owon:
Jesu sanu fun wa.
Verse 8
Je k’ a pin ‘nu iya Re,
K’ a ma ko iku fun O,
Je k’ a ri ‘toju Re gba;
Jesu sanu fun wa.
Verse 9
Ki gbogbo awa tire,
Je omo ile kanna,
“Tori Re k’a fe ‘ra wa:
Jesu sanu fun wa.
Verse 10
Jesu ‘Wo ti eru nba,
‘Gbat’ osi ‘Wo nikan,
Ti okunkun su bo O:
Jesu sanu fun wa.
Verse 11
‘Gbati a ba npe lasan,
T’ ireti wa si jina;
N’nu okun na di wa mu
Jesu sanu fun wa.
Verse 12
B’ o dabi Baba ko gbo,
B’ o dabi ‘mole ko si,
Je ka fi ‘gbagbo ri O,
Jesu sanu fun wa.
Verse 13
Jesu ninu ongbe Re,
Ni ori agbelebu,
‘Wo ti o few a sibe;
Jesu sanu fun wa.
Verse 14
Ma kongbe ife Re
Sise mimo lara wa,
Te ife Re na l’ orun
Jesu sanu fun wa.
Verse 15
Je k’ a kongbe ife Re
Ma samona wa titi,
Sibi omi iye ni;
Jesu sanu fun wa.
Verse 16
Jesu Olurapada,
‘Wo t’ o se ‘fe Baba Re,
T’o si jiya ‘tori wa;
Jesu sanu fun wa.
Verse 17
Gba wa l’ ojo idamu,
Se oluranlowo wa,
Lati ma t’ ona mimo;
Jesu sanu fun wa.
Verse 18
F’ imole Re s’ ona wa,
Ti v’ o ma tan titi lai,
Tit’ ao fi de odo Re:
Jesu sanu fun wa.
Verse 19
Jesu gbogbo ise Re,
Gbogbo Damu Re pin,
O Jowo emi Re lowo;
Jesu sanu fun wa.
Verse 20
‘Gbat’ iku ba de ba wa,
Gba wa lowo ota wa;
Yo wa ni wakati na,
Jesu sanu fun wa.
Verse 21
Ki iku at’ iye Re,
Mu ore ofe ba wa,
Ti yio, mu wa d’oke:
Jesu sanu fun wa.
ConversationA memory, a prayer, a word of encouragement.0 reflections
Every hymn has a story. What is yours?
Share a memory, a prayer or the words that stayed with you. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.