GBO-GB’ ogo iyin ola
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
GBO-GB’ ogo iyin ola,
Fun O oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!
‘Wo l’ Oba Israeli,
Om’ Alade Dafidi,
T’ O wa l’ Oko Oluwa,
Oba olubukun.
Gbogb’ ogo iyin ola
Fun O, Oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!
Verse 2
Egbe awon maleka,
Nyin O l’ oke giga;
Awa at’ eda gbogbo
Si dapo gberin na.
Verse 3
Awon Hebru lo, saju,
Pelu imo ope,
Iyin, adura, at’ orin,
L’ a mu wa ‘waju Re.
Verse 4
Si O saju iya Re,
Nwon korin iyin won;
‘Wo t’a gbega nisiyi,
L’ a nkorin iyin si.
Verse 5
‘Wo gba orin iyin won:
Gb’ adura t’a mu wa,
‘Wo ti nyo s’ ohun rere,
Oba wa Olore.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.