WO t’ O teriba nin’ odo Jordani
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
WO t’ O teriba nin’ odo Jordani,
T’ O mokun n’nu ‘banuje wa, t’ O si ku
T’ O jinde ninu okunkun sin’ ogo,
T’ O si gba ‘joba ife awon Tire.
Verse 2
Ona Re l’ a ntele si inu odo,
K’ a sin wa pelu Re ninu iku Re,
T’ a si ji l’ aworan Re k’ a le t’ ona
T’ o nfi gbogb’ agbara dan s’ ojo mole.
Verse 3
Jesu Olugbala, ‘Wo Oluwa wa,
Nipa ijiya at’ oro anu Re,
Gba wa la, ki O si ma gbe inu wa,
K’ O p’ okan wa mo kuro inu ese.
Verse 4
K’ a to gb’ ade ogo at’ imo lowo,
At’ aso ala t’ eje Jesu ti fo,
A dapo mo awon mimo t’ o ti lo,
Ninu ‘yanu, lati bukun O titi lai.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.