Yoruba Baptist Hymns
OLUWA orun at’ aiye
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
OLUWA orun at’ aiye!
Jesu, Omo ninu ara!
Emi Mimo fun ‘toju wa!
E gbo, ki E si gb’ eje wa.
Verse 2
A gba O, Jesu ti a pa,
A gba ‘Wo t’ O r’ oke orun;
Pelu Re a ti ku s’ ese,
Okan wa si nfe ba O ji.
Verse 3
A gba ihinrere Re gbo,
A nlo, owo Re yio to wa;
L’ odo Jordani a nw’ ona
T’ awon Tire gba d’ odo Re.
Verse 4
Nipa ‘tebomi – ami nla –
Awa fi ara wa fun O
F’ edidi te majemu na,
K’ O gba wa fun Tire lailai.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/oluwa-orun-at-aiye/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.