Yoruba Baptist Hymns
IBUKUN ni f’ oku
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
IBUKUN ni f’ oku,
T’ o simi le Jesu;
Awon t’ o gb’ ori won
Le okan aiya Re.
Verse 2
Iran ‘bukun l’ eyi,
Kosi boju larin;
Nwon ri En’ Imole,
Jesu Olugbala.
Verse 3
Nwon bo lowo aiye,
Pelu aniyan re;
Nwon bo lowo ewu,
T’ o nrin l’ osan, l’ oru.
Verse 4
Lori iboji won,
L’ awa nsokun loni,
Nwon j’ en’ ire fun wa,
T’ a ki o gbagbe lai.
Verse 5
A k’ yo gbohun won mo,
Ohun ife didun;
Lat’ noi lo, aiye
Ki o tun mo won mo.
Verse 6
Eyin oninure
A fi wa sile lo;
Ao sokun nyin titi,
Jesu pa sokun ri.
Verse 7
Sugbon a fe gbohun
Olodumare na;
Y’ o ko, y’o si wipe,
E dide, e si yo.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/ibukun-ni-f-oku/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.