1. MO duro de Olorun mi,
O si gbo igbe mi,
O ri mo simi l’ oro Re,
O si mu ‘gbala wa.
2. O yo mi l’ ogbun okunkun,
Nibiti mo ns’ ofo,
O si yo ese mi kuro
Ninu afo ese
3. O gbe mi s’ ori apata,
O si ko ahon mi,
Lati yin ise owo Re,
Pelu orin ope.
4. Bi iyonu Re ti po to!
B’ anu Re ti ga to!
Oro at’ aye wa ko to
Lati ka iye won.
(Visited 296 times, 1 visits today)