← Back to the hymnbook
Yoruba Baptist Hymns No. 209

NIGBAT’ idanwo yi mi ka

Read. Sing. Share.

Verse 1

NIGBAT’ idanwo yi mi ka,
T’ idamu aiye mu mi,
Ti Esu wa bi ore mi,
Lati wa iparun mi.
Oluwa, jo masai pe mi,
B’ O ti p’ Adam n’nu ogba,
Pe, “Nibo l’ owa, elese?”
Ki nle bo ninu egbe.

Verse 2

Nigbat’ esu mu ‘tanje re
Gbe mi g’ or’ oke aiye,
T’ o ni ki nteriba fun on
K’ ohun aiye je t’ emi.

Verse 3

N’gba bilisi fi tulasi
Fe mu mi y’ ase Re da,
T’ o duro gangan l’ ehin mi,
N’ ileri pe ko si nkan.

Verse 4

Nigbati mo ba fe to ‘pa
‘Damoran on ‘fe ‘nu mi,
T’ okan mi nse kilakilo,
Ti nko tutu, nko gbona.

Verse 5

Nigbati k s’ alabaro,
T’ olutunu si jina,
T’ ibanuje ja mi gbongbon
Bi iyo ninu okun,

Verse 6

Nigba bi aja ti ko gbo
Fere ti olode mo,
Sonu s’ aginju aiye lo,
Latin’ ireti ipada,

Verse 7

Nigbati igbekele mi
Di t’ ogun at’ orisa,
T’ ogede di adura mi,
T’ ofo di ajisa mi,

Conversation 0 comments

Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.

Share anonymously

No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.

Where are you joining from?

Your city and country appear beside your anonymous comment after review.

Form verification is provided by Cloudflare Turnstile.

Sign in to keep track of replies

Report a lyric correction

Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.

Form verification is provided by Cloudflare Turnstile.Your details are used to respond to this submission.
Support the archive