1. OLUSAGUTAN ni npe mi,
Kuro nin aginju ese,
On p’ agutan t’ o sako lo
Jina rere sinu agbo.
Refrain
Mu won wa, mu won wa,
Mu won wa, kuro l’ oko ese;
Mu won wa, mu won wa,
M’ asako wa sodo Jesu.
2. Ran Olusagutan lowo
Lati wa ‘gutan re t’ o nu,
Mu awon t’ o nu pada wa,
Sin ‘agbo kuro l’ otutu.
Refrain
Mu won wa, mu won wa,
Mu won wa, kuro l’ oko ese;
Mu won wa, mu won wa,
M’ asako wa sodo Jesu.
3. Gbo igbe won nin’ aginju,
Ati lori oke giga,
Gb’ olusagutan nwi fun o,
“Lo mu agutan mi wole.”
Refrain
Mu won wa, mu won wa,
Mu won wa, kuro l’ oko ese;
Mu won wa, mu won wa,
M’ asako wa sodo Jesu.
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.
Support the Hymn Archive