1. MO n’ ‘ore, kan, A, Ore na!
N’ ife mi k’ emi to mo,
On f’ okun ife Re nla,
Fa mi sunmo odo Re,
Ka okan mi n’ ife nla na
N’ ide ti nkan ko le tu,
Mo di Tire, on je t’ emi,
L’ aiye yi titi lailai.
2. Mo n ‘Ore kan, A, Ore na!
O ku fun igbala mi;
Iye nikan ki On fun mi,
On si fara Re fun mi,
Ko s’ ini mi t’o nse temi,
Tire ni gbogbo won je;
Okan ati agbara mi,
Tire ni titi lailai.
3. Mo n ‘Ore kan, A, Ore na!
Gbogb’ agbara ni Tire;
Lati pa mi mo l’ona mi,
Ki On si mu mi d’ orun,
Ogo ailopin ‘le nah an,
Fun irunu Okan mi,
Lehin lala ogun aiye,
Ngo simi titi lailai.
4. Mo n ‘Ore kan, A, Ore na!
J’ oloto at’ alanu,
Oludamoran rere ni
O ni ‘pa olugbija,
Kuro lod eniti o fe mi,
Tal’ o le ya okan mi,
Niye, niku, l’ aiye, l’ orun,
Tire ni titi lailai.
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.
Support the Hymn Archive