AFRIK’ ‘le wara at’ oyin
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
AFRIK’ ‘le wara at’ oyin,
Ni orile aiye now si,
T’ Olorun fun ania dudu,
Fun ini re titi lailai.
Verse 2
Ote owo-eru ‘gbani,
Ko f’ okan baba wa bale,
A ko won lo lairotele,
Nwon s’ eru, oju sip on won.
Verse 3
Ose at’ ekun gb’ ile kan,
Gb’ oko, aya, baba, omo,
Fi tulasi, ‘daro, pinya,
At’ edun t’ enu ko le so.
Verse 4
Sugbon b’ Olorun Olore
Ti ranti Isreal nigbani,
O s’ona igbala fun won,
Nwon d’ omnira, omo Kristi.
Verse 5
Sibe opo gbagbe ‘le won,
Oluwa a mbe, se ‘ranwo,
Mu won pada si ile won;
Ka si le tubo ma yin O.
Verse 6
Eko, ‘laju ‘gbagbo pipe,
Irepo at’ ife toto,
Rojo won lat’ odo Re wa,
S’ ori gbogbo ‘le Afrika.
Verse 7
Oluwa Olodumare,
Je k’ ile wa wulo fun wa,
Gbati ‘se wa l’aiye ba pin,
Gba wa s’ orun alafia.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.