YBH 352

OM’-OGUN Krist’ dide.

1. OM’-OGUN Krist’ dide
Mu ‘hamora nyin wo;
Mu ‘pa t’ Olorun fi fun nyin,
Nipa ti Omo Re.

2. Gbe ‘pa Olorun wo,
T’ Oluwa om’-ogun;
Enit’ o gbeleke Jesu,
O ju asegun lo.

3. Ninu ipa Re nla,
On ni ki e duro,
Tori k’ e ba le ija na,
E di ‘hamora nyin.

4. Lo lat’ ipa de ‘pa,
Ma ja, ma gbadura,
Te agbara okunkun ba,
E ja k’ e si segun.

5. Sibe jek’ Emi ke
N’n awon om’-ogun, “Wa,”
Titi Jesu yio sokale;
T’ yio m’ asegun lo l’e.

(Visited 1,190 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you