YBH 564

OLORI ijo t’ orun

1. OLORI ijo t’ orun,
L’ ayo l’ a wole fun O;
K’ o to de, ijo t’ aiye,
Y’o ma korin bi t’ orun,
A gbe okan wa s’ oke,
N’ ireti t’ o n’ ibukun;
Awa kigbe, awa f’ iyin
F’ Olorun igbala wa.

2. Bi a wa ninu ‘ponju,
T’ a nkoja ninu ina,
Orin ife l’ awa o ko.
Ti o mu wa sunmo O;
Awa sape, a si yo,
Ninu ojurere Re
Ile t’ o so wa di Tire,
Y’o pa wa mo titi lai.

3. Iwo mu awon enia Re
Koja isan idanwo;
A ki o beru wahala,
‘Tori O wa nitosi,
Aiye, ese at’ Esu,
Kojuja si wa lasan,
L’ agbara Re, a o segun,
A o si ko ‘rin Mose.

4. Awa f’ igbagbo r’ ogo,
T’ O nfe lati fi wa si,
A kegan ere aiye,
Ti a fi siwaju wa,
Bi O ba si ka wa ye,
Awa pelu Stefen t’o ku
Y’o ri O bi o ti duro
Lati pe wa lo s’ orun.

(Visited 31,753 times, 42 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you