1. MA sun lo, olufe; sa ma simi,
F’ ori re le aiya Olugbala;
A fe o, sugbon Jesu fe o ju:-
O di owuro o!
2. Orun re dun bi orun omode,
B’ o si ji ekun ko si fun o mo,
Isimi t’o daju n’ isimi re,
O di owuro o!
3. Titi okunkun aiye y’o fi tan,
Titi ao fi ko ikore wo ‘le;
Titi oye aiye yio fi la,
O di owuro o!
4. Titi orun ajinde y’o fi yo,
Ti awon oku Jesu y’o dide;
Ti On y’o de ninu ola nla Re,
O di owuro o!
5. Titi ewa orun y’o je tire,
Ti iwo o ma tan ninu ogo,
Ti Oluwa y’o fi de o l’ ade,
O di owuro o!
6. O d’ owuro sa ni, olufe mi,
A tun fere ri ‘ra na n’ ibiti
Ipinya ati ituka ko si,
O di owuro o!
7. Tit’ ao fi pade niwaju ite,
Nin’ aso igunwa awon Tire,
Titi a o fi riran kedere,
O di owuro o!
(Visited 23,145 times, 3 visits today)