1. RANSE Olorun seun;
Simi n’nu lala re;
Iwo ti ja, o si segun;
Bo s’ ayo Baba re,
Ohun na de l’ oru,
O dide lati gbo;
Ofa iku si wo l’ ara,
O subu, ko beru.
2. Igbe ta l’ oganjo
“Pade Olorun re.”
O ji o ri Balogun re
N’n’ adura on ‘gbagbo, –
Okan re nde wiri,
O bo amo sile
Gbat’ ile mo, ago ara
Si sun sile l’ oku.
3. Rora iku koja,
Lala at’ ise tan;
Ojo ogun j ija pari,
Okan re r’ Alafia,
Omo-‘gun Krist’, o seun!
Ma korin ayo sa!
Simi lodo Olugbala,
Simi titi aiye.
(Visited 2,720 times, 1 visits today)