1. ITANA t’ o bo ‘gbe l’ aso,
T’o tutu yoyo be;
Gba doje ba kan, a si ku,
A subu, a siro.
2. Apere yi ye f’ ara wa,
B’ or’ Olorun ti wi;
K’ omode at’ agbalagba
Mo ‘ra won l’ eweko.
3. A! ma gbakele emi re,
Ma pe ‘gba re n’ tire;
Yika l’ a nri doje iku,
O nbe ‘gberun lu ‘le.
4. Enyin t’ a da si di oni,
Laipe, emi y’o pin,
Mura k’ e sig bon l’ akoko,
K’ iko iku to de.
5. Koriko, b’ o ku, ki ji mo;
E ku lati tun ye;
A! b’ iku lo je ‘lekun nko
S’ irora ailopin.
6. Oluwa, jek’ a j’ ipe Re,
K’ a kuro n’nu ese;
Gbat’ a lu ‘le bi koriko,
K’ okan way o si O.
(Visited 693 times, 1 visits today)