YBH 507

GBAT’ a kun fun ‘banuje,

1. GBAT’ a kun fun ‘banuje,
Gb’ omije nsan l’ oju wa,
Gbat’ a nsokun, t’ a nsofo,
Olugbala, gbo ti wa.

2. ‘Wo ti gbe ara wa wo;
O si mo ‘banuje wa;
O ti sokun bi awa,
Olugbala, gbo ti wa.

3. ‘Wo ti teriba fun ‘ku;
‘Wo ti t’ eje Re sile;
A te O si posi ri;
Olugbala, gbo ti wa.

4. Gbat’ okan wa ba baje,
Nitori ese t’ a da;
Gbat’ eru ba b’ okan wa,
Olugbala, gbo ti wa.

5. ‘Wo o ti mo eru ese,
Ese ti ki se Tire;
Eru ese na l’ O gbe,
Olugbala, gbo ti wa.

6. Oti s’ ilekun iku,
O ti s’ etutu f’ ese,
O wa low’ otun Baba,
Olugbala, gbo ti wa.

(Visited 554 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you