YBH 506

O SUN,” ni Jesu wi

1. “O SUN,” ni Jesu wi
Nipa ti Lasaru,
Enit’ o ku, ti a ti san,
T’ a ti te s’ iboji.

2. Oku ojo merin,
L’ oju Jesu, sun ni,
On l’ Ajinde ati Iye
F’ awon t’ o gba A gbo.

3. Ore Je ski ku,
Nwon a ma parade,
Kuro ni kokoro ile,
S’ ohun ti nfo l’ oke.

4. Sun, ara, olufe,
Jesu duro ti o,
Ma foya, O ti se ‘leri,
Ajinde f’ eni Re.

5. O fere gb’ ohun na,
Lat’ oju orun re,
Ohun didun Jesu ti yio
Pe o si isoji.

6. A ko ni b’ ara je
Bi alain’ ireti,
O d’ owuro l’ a le ki o,
Sun re, ara, sun re.

7. Awa pelu yio sun
Li akoko ti wa;
A! k’ ile mo ba gbogbo wa
L’ese Olugbala.

(Visited 951 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you