1. IKU l’ opin ohun gbogbo;
B’ o ti wu k’ emi gun,
Egun ni ko le sai ma se
T’ a ti fi eda gun.
2. Lehin ojo die l’ aiye,
T’ a lo ninu lala,
Ninu aisan at’ ailera,
Iko iku yio de.
3. Erin l’ oro, ekun l’ ale,
Ayo on ‘banuje,
Ojo ebi, ojo ayo
L’ opin ninu iku.
4. A! egun ‘re f’ awon t’ o ku
Ninu Olugbala;
Nwon ku si iponju gbogbo,
Nwon ji sinu ogo.
5. Ona l’ o je sinu iye
F’ awon onigbagbo,
Tani few a nihin titi
Ninu aisimi yi?
6. Gba wa lowo iku keji,
Jesu Olugbala,
K’ a r’ iye ninu iku Re,
Lehin lala aiye.
(Visited 1,133 times, 1 visits today)