YBH 511

KI a to d’ awon oke nla

1. KI a to d’ awon oke nla,
Tabi ki aiye to duro,
Ki a to da awon igba,
‘Wo l’ Olorun lat’ ibere.

2. Egberun odun l’ oju Re
Dabi ana, bi nwon ti nlo,
Ana, oni, ati ola,
Nwon sipaya niwaju Re.

3. Oj’ aiye wa dabi ala,
Bi ero okan ti ki pe,
Ti sa pelu ‘mole oro,
A si f’ okan ‘ronu sile.

4. Oluwa, fun wa ni ogbon
K’ a le l’ akoko war ere,
Nigbose, k’ a le ba O gbe
Nib’ iye at’ ayo ki pin.

(Visited 457 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you