1. LALA alagbase tan;
Ojo ogun ti pari;
L’ ebute jinjin rere
Ni oko re ti gun si;
Baba labe itoju Re
L’ awa f’ iranse Re yi si.
2. Nibe l’ a re won l’ ekun
Nibe nwon m’ ohun gbogbo;
Nibe l’ Onidaj’ Oto
Ndan ise aiye won wo
3. Nibe l’ olus’ agutan
Nko awon agutan lo
Nibe l’o ndabobo won
Koriko ko le de ‘be
4. Nibe l’ awon elese
T’ o teju m’ agbelebu
Y’ o mo ife Kristi tan,
L’ ese Re n’ Paradise
5. Nibe l’ agbara Esu
Ko le b’ ayo won je mo;
Kristi Jesus a nso won,
On t’ O ku fun ‘dande won,
6. “Erupe fun erupe,”
L’ ede wa nisisiyi;
A te sile lati sun
Titi d’ ojo ajinde.
(Visited 1,608 times, 1 visits today)