YBH 513

IBUKUN ni f’ oku

1. IBUKUN ni f’ oku,
T’ o simi le Jesu;
Awon t’ o gb’ ori won
Le okan aiya Re.

2. Iran ‘bukun l’ eyi,
Kosi boju larin;
Nwon ri En’ Imole,
Jesu Olugbala.

3. Nwon bo lowo aiye,
Pelu aniyan re;
Nwon bo lowo ewu,
T’ o nrin l’ osan, l’ oru.

4. Lori iboji won,
L’ awa nsokun loni,
Nwon j’ en’ ire fun wa,
T’ a ki o gbagbe lai.

5. A k’ yo gbohun won mo,
Ohun ife didun;
Lat’ noi lo, aiye
Ki o tun mo won mo.

6. Eyin oninure
A fi wa sile lo;
Ao sokun nyin titi,
Jesu pa sokun ri.

7. Sugbon a fe gbohun
Olodumare na;
Y’ o ko, y’o si wipe,
E dide, e si yo.

(Visited 1,303 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you