YBH 368

JESU mo bg’ agbelebu mi

1. JESU mo bg’ agbelebu mi,
Ki nle ma to O lehin;
Otosi at’ eni egan,
‘Wo l’ ohun gbogbo fun mi;
Bi ini mi gbogbo segbe,
Ti ero mi gbogbo pin,
Ibe oloro ni mo je!
T’emi ni Krist’ at’ orun.

2. Eda le ma wahala mi,
Y’ o mu mi sunmo O ni;
Idanwo aiye le ba mi
Orun y’o mu ‘simi wa,
Ibanuje ko le se nkan
B’ ife Re ba wa fun mi;
Ayo ko si le dun mo mi,
B’ Iwo ko si ninu re.

3. Okan mi, gba igbala re,
Bori ese at’ eru,
Ma sise, si ma ipokipo,
Ma sise, si ma jiya;
Ro t’ Emi to wa ninu re;
At’ ife Baba si o;
W’ Olugbala to ku fun o;
Omo orun mase kun!

4. Nje koja lat’ ore s’ogo,
N’n adura on igbagbo;
Ojo ailopin wa fun o,
Baba y’o mu o de ‘be,
Ise re l’ aiye fere pin,
Ojo ajo re mbuse
Ireti yo pada s’ ayo,
Adura s’ orin iyin.

(Visited 23,839 times, 7 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you