1. JESU, Oba nla ni Sion,
‘Wo ni yio j’ amona wa;
Ase Re li a gbekele,
Iwo nikan l’ ao tele.
2. Bi apere ijiya ‘Re,
At’ isegun lor’ iku,
Awa t’ o mo igbala Re,
A te wa ri n’nu odo.
3. L’ aiberu egan araiye,
A nto ‘pa ona lailai,
A sin wa po pel’ Oluwa,
A si ji s’ iye titun.
(Visited 965 times, 1 visits today)