1. IWO oro t’o tobi,
Ninu eyit ‘a ri,
Ileri ati sise
Awamaridi ni:
Nigba ekun at’ ayo,
Idanwo at’ eru,
Mo gbo Jesu wipe, “Wa”
Mo si lo sodo Re.
Wa, wa sodo Mi,
Wa, wa sodo Mi,
Alare t’ orun nwo,
Wa, wa sodo Mi.
2. Emi mi, ma sako lo
Kuro lod’ Ore yi
Sunmo O, a sunmo O,
Ba gbe titi d’ opin;
A! alailera l’emi
Ese mi papoju
Mo nsako nigbagbogbo
Mosi tun pada wa.
3. Mo fe ma sunm’ odo Re,
Ki “Wa” yi ba le je
Ohun ti a fo jeje
Fun enit’ o sunmo O:
Okun ati oke nla
Ki yio da mi duro
Lati di owo Re mu
Gbati o wipe, “Wa,”
(Visited 644 times, 1 visits today)