YBH 365

TORI Mi at’ ihinrere

1. TORI Mi at’ ihinrere,
E lo so t’ Irapada;
Awon onse Re nke “Amin”
Tire ni gbogbo ogo;
Nwon nso t’ibi tiya t’iku,
Ife etutu nla Re;
Nwon ka ohun aiye s’ofo
T’ajinde on ‘joba Re.

2. Gbo gbo ipe ti Jubili
O ndun yi gbogb’ aiye ka;
N’ile ati loju okun
A ntan ihin igbala,
Bi ojo na ti nsumole,
T’ ogun si ngbona janjan,
Imole Ila orun na,
Y’o mo larin okunkun.

3. Siwaju ati siwaju
Lao ma gbo Alleluya,
Ijo ajagun y’o ma yo,
Pel’ awon Oku mimo;
A fo aso won n’nu eje,
Duru wura won si ndun;
Aiye at’ orun d’ohun po,
Nwon nko orin isegun.

4. O de, Enit’ a nw ‘ona Re,
Eni ikehin na de,
Immanueli to d’ade,
Oluwa awon mimo,
Iye, Imole at ‘Ife,
Metalokan titi lai,
Tire ni Ite Olorun
Ati t’ Odo agutan.

(Visited 1,919 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you