YBH 364

IWE kan wa ti kika ra

1. IWE kan wa ti kika ra,
Ko soro fun enia,
Ogbon ti awon t’o ka nfe,
Ni okan ti o mo.

2. Ise gbogbo t’Olorun se
L’oke n’ile n’nu wa;
Nwon j’okan ninu iwe na,
Lati f’Olorun han.

3. Imole osupa l’oke,
Lat’odo orun ni;
Be l’ogo Ijo Olorun,
T’odo Olorun wa.

4. Oruko t’o j’oruko lo
Ti gbogb’aiye nke pe,
Awon okun si nsape fun,
Angeli nkorin fun.

5. Or’ ofe dab’iri orun,
Jeje li o si nwa,
N’ibi t’ Olorun bad a si,
Alafia wa nibe.

6. Iwo ti oje ki a ri,
Ohun t’o dara yi;
Fun wa l’ okan lati wa O,
Olorun Baba wa.

(Visited 576 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you