YBH 363

IWO Oro Olorun

1. IWO Oro Olorun,
Ogbon at’ oke wa,
Oto ti ki ‘yipada,
Imole aiye wa;
Awa yin O fun ‘mole,
T’ inu iwe mimo;
Fitila fun ese wa,
Ti ntan titi aiye.

2. Oluwa l’ o f’ ebun yi
Fun ijo Re l’aiye;
A ngbe ‘mole na s’oke
Lati tan y’aiye ka,
Apoti wura n’ise,
O kun fun Otito;
Aworan Kristi si ni,
Oro iye toto.

3. O nfe lele b’ asia,
T’a ta loju okun;
O ntan b’ina alore,
Si okunkun aiye;
Amona enia ni,
Ni wahala gbogbo,
Nin ‘arin omi iye
O nto wa s’odo Krist.

4. Olugbala, se ‘jo Re,
Ni fitila wura;
Lati tan imole Re,
Bi aiye igbani;
Ko awon ti o sako,
Lati lo ‘mole yi;
Tit’ okun aiye y’o pin,
Ti n won o roju Re.

(Visited 986 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you