YBH 362

BIBEL’ iwe aiyeraiye

1. BIBEL’ iwe aiyeraiye
Tani le ridi re?
Tani le so idide re?
Tani le m’ opin re?

2. Asiri olodumare;
Iko Oba orun
Ida t’o pa oro iku;
Aworan Olorun.

3. Okan ni O l’ arin opo
Iwe aiye ‘gbani,
Iwo l’ o s’ ona igbala
Di mimo f’ araiye.

4. Isura ti Metalokan,
Oba nla t’ o gunwa;
Jo tumo ara Re fun mi
Ki ‘m’ye siyemeji.

5. Ki ‘m si O pelu adura,
Ki ‘m’keko ninu re;
Iwo iwe aiyeraiye
F’ife Jesu han mi.

(Visited 801 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you