1. BAWO ni awon ewe wa,
Y’o ti ma sora won;
Bikose “nipa ‘kiyesi,
Gege bi oro Re,”
2. ‘Gba oro na wo ‘nu okan;
A tan imole ka;
Oro na ko ope l’ ogbon
At’ imo Olorun.
3. Orun ni, imole wa ni,
Amona wa l’osan;
Fitila ti nfonahan wa,
Ninu ewu oru.
4. Oro Re, oto ni titi,
Mimo ni gbogbo re;
Amona wa l’ojo ewe,
Opa l’ojo ogbo.
(Visited 454 times, 1 visits today)