1. BABA orun, ti ife Re
B’ okan wa, wa irapada,
A teriba niwaju Re,
Jo fun wa n’ idariji Re.
2. Om’ Olorun Alagbara,
Woli at’ Olugbala wa,
‘Waju ‘te Re l’ a teriba,
Masai fun wa n’ igbala Re.
3. Emi Mimo, Enit” o mi,
T’ okan ji n’n ese at’ iku,
‘Waju ‘te Re l’ a teriba,
Jo fun wa n’ ipe ‘soji Re.
4. Baba, Omo, Emi Mimo,
Ori kan lai, Metalokan, –
‘Waju ‘te Re l’ a teriba;
Masai f’ emi iye fun wa.
(Visited 612 times, 1 visits today)