1. BIBELI mimo t’ orun
Owon isura t’ emi!
‘Wo ti nwi bi mo ti ri,
‘Wo ti nso bi mo ti wa.
2. ‘Wo nko mi, bi mo sina,
‘Wo nf’ ife Oluwa han;
‘Wo l’ o si nto ese mi,
‘Wo l’ o ndare at’ ebi.
3. ‘Wo ni ma tu wa ninu,
Ninu wahala aiye;
‘Wo nko ni, nipa ‘gbagbo
Pe a le segun iku.
4. ‘Wo l’ o nso ti mbo,
At’ iparun elese;
Bibeli mimo t’ orun,
Owon isura t’ emi.
(Visited 3,668 times, 2 visits today)