1. A, JEKI oro mimo Re
Fi agbara si okan mi,
F’ imole at’ ife orun
Wi f’ okan mi pe, “Wo t’ emi.”
2. Oro Re t’ o kun fun ayo,
Yio le eru mi s’ apakan;
‘Reti orun didan y’o si
F’ ayo mole li oru yi.
3. Emi mi y’o si f’ ayo fo
N’nu ‘gbagbo ga ju sanma lo;
Nigb’ ohun sa ba si koja
T’ aiye asan ko tan ni mo. –
4. A, ki nle de ‘bi ayo ni,
Nibit’ ogo Re gbe joba,
Ki nwa leba ite Re lai
L’ ayo t’ aiye ko le ronu.
(Visited 507 times, 1 visits today)