1. BABA orun, nin’ oro Re
Ni ogo orun ntan;
Titi lai l’ a o ma sin O,
Fun Bibeli mimo.
2. Opo ‘tunu wa ninu re,
Fun okan alare;
Gbogbo okan ti ongbe ngbe,
Nri omi iye mu.
3. Ninu re l’ alafia wa,
Ti Jesu fi fun wa;
Iye ainipekun si wa
N’nu re fun wa gbogbo
4. Iba le ma je ayo mi,
Lati ma ka titi;
Ki nma ri ogbon titun ko,
N’nu re lojojumo.
5. Oluwa, Oluko orun,
Mase jina si mi;
Ko mi lati fe oro Re,
Ki nri Jesu nibe.
(Visited 788 times, 1 visits today)