1. DURO, duro fun Jesu,
Enyin om’ogun Krist’:
Gbe asia Re s’ oke,
A ko gbodo fe ku;
Lat’ isegun de ‘segun
N’ y’o ma to ogun Re;
Tit’ ao segun gbogb’ ota,
Ti Krist’ y’o j’ Oluwa.
2. Duro, duro fun Jesu,
F’ eti s’ ohun ipe;
Jade lo s’ oju ija
L’ oni ojo nla Re;
Enyin akin ti nja fun
Larin ainiy’ ota
N’nu ewu e ni ‘gboiya
Dojuko agbara.
3. Duro, duro fun Jesu,
Duro l’ agbara Re;
Ipa enia ko to,
Ma gbekele tire;
F’ ihinrere hamora
Ma sona, ma gbadua,
B’ ise tab’ ewu ba pe,
Ma se alai de ‘be.
4. Duro, duro fun Jesu;
Ija na ki y’o pe;
Oni, ariwo ogun,
Ola, orin ‘segun;
Enit’ o ba si segun,
Y’o gba ade iye;
Y’o ma ba Oba Ogo
Joba titi lailai.
(Visited 9,366 times, 1 visits today)