1. KRISTIAN ma ti wa ‘simi,
Beli angeli re nwi,
Ni arin ota l’ owa,
Ma sora.
2. Ogun orun apadi,
T’ a ko ri nko ‘ra won jo;
Nwon nso ijafara re,
Ma sora.
3. Wo ‘hamora orun re,
Wo l’ osan ati l’ oru,
Esu ba, o ndode re,
Ma sora.
4. Awon t’ o segun saju,
Nwon now wa b’ awa ti nja,
Nwon nfi ohun kan wipe,
Ma sora.
5. Gbo b’ Oluwa re ti wi,
Eniti iwo feran,
F’ oro Re si okan re,
Ma sora.
6. Ma sora bi enipe
Nibe n’ isegun re wa;
Gbadura fun ‘ranlowo,
Ma sora.
(Visited 7,855 times, 4 visits today)