YBH 563

IGBAGBO l’ ategun t’ o so

1. IGBAGBO l’ ategun t’ o so
Orun at’ aiye po;
On l’ Olugbala fi sise
Iyanu Re l’ aiye.

2. Igbagbo ni keke Enok’
Ti o gun lo s’ orun;
On l’ o gba Ju meta ni la,
L’ ogba Daniel pelu.

3. Lor’ igbagbo ni Noa ko
Oko igbala ni;
On l’ agbara t’ o gb’ Elija
Wo inu samma lo.

4. Igbagboo n’ ipile ‘reti,
O le se ohun nla;
Otito igbagbo le mu
Ohun ti ko si wa.

5. On l’ agbara ase ‘kini
T’ o mu ki aiye wa;
On l’ agbara ikehin ti
Yio gba elese la.

6. “K’ o ri fun o b’ igbagbo re,”
L’ Olugbala wa wi,
A! je ki ngba ohun nla gbo
Si O, Oluwa mi.

(Visited 1,129 times, 3 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you