YBH 562

OM’ Olorun, a ko ri O

1. OM’ Olorun, a ko ri O,
‘Gbat’ O wa s’ aiye iku yi;
Awa ko ibugbe Re,
Ni Nasareti ti a gan;
Sugbon a gbagbo p’ ese Re,
Ti te ta re kakiri.

2. A ko ri O lori igi,
T’ enia buburu Re,
A ko gbo igbe Re wipe,
“Dariji won ‘tor’ aimo won,”
Sibe, a gbagbo pe ‘ku Re
Mi aiye, o si m’ orun su.

3. A ko duro let’ iboji,
Nibiti a gbe te O si;
A ko joko n’nu yara ni,
A ko ri O loju ona;
Sugbon a gbagbo p’ angeli
Wipe, “Iwo ti ji dide.”

4. A ko r’ awon wonni t’ O yan
Lati ri ‘goke r’ orun Re;
Nwon ko fi iyanu w’ oke,
Nwon si f’eru dojubole:
Sugbon a gbagbo nwon ri O,
Bi O ti ngoke lo s’ orun.

5. Iwo njoba l’ oke loni,
‘Wo si nbukun waon Tire,
Imole ogo Re ko tan
Si aginju aiye wa yi;
Sugbon, a gba oro Re gbo,
Jesu, Olurapada wa.

(Visited 473 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you