1. JESU l’ Olusagutan mi,
Ore Eniti ki ye!
Ko s’ ewu bi mo je Tire,
T’ On sije t’ emi titi.
2. Nib’ odo omi iye nsan
Nibe l’ o nm’ okan mi lo;
Nibiti oko tutu nhu
L’ O nf’ onje orun bo mi.
3. Mo ti fi were sako lo,
N’ ife, O si wa mi ri;
L’ ejika Re l’ O gbe mi si,
O f’ ayo mu mi wa ‘le.
4. Nko beru ojiji iku
B’ Iwo ba wa lodo mi;
Ogo Re ati opa Re
Awon l’ o ntu mi ninu.
5. Iwo te tabili fun mi;
‘Wo d’ ororo s’ ori mi;
A! ayo na ha ti po to!
Ti nt’ odo Re wa ba mi.
6. Be lojo aiye mi gbogbo
Ore Re ki y’o ye lai;
Olusagutan ngo yin O,
Ninu ile Re titi.
(Visited 4,606 times, 1 visits today)