YBH 613

KI se l’ ainireti

KI se l’ ainireti,
Ni mo to o wa,
Ki se l’ aini ‘gbagbo,
Ni mo kunle;
Ese ti gori mi,
Eyi sa l’ ebe mi,
Eyi sa l’ ebe mi,
Jesu ti ku.

2. A! ese mi poju
O pon koko;
Adale, adale,
Ni mo ndese!
Ese aiferan Re;
Ese aigba O gbo;
Ese aigba O gbo;
Ese nlanla!

3. Oluwa mo jewo
Ese nla mi;
O mo bi mo ti ri;
Bi mo ti wa;
Jo we ese mi nu!
K’ okan mi mo loni,
K’ okan mi mo loni;
Ki ndi mimo.

4. Olododo ni O,
O ndariji;
L’ ese agbalebu,
Ni mo wole;
Je k’ eje iwenu,
Eje Odagutan,
Eje Oduagutan;
We okan mi.

5. ‘Gbana Alafia
Y’ o d’ okan mi;
‘Gbana ngo ba O rin,
Ore airi;
Em’ o f’ ara ti O;
Jo ma to mi s’ ona,
Jo ma to mi s’ ona,
Titi aiye.

(Visited 314 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you