Yoruba Baptist Hymns
BABA orun, nin’ oro Re
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
BABA orun, nin’ oro Re
Ni ogo orun ntan;
Titi lai l’ a o ma sin O,
Fun Bibeli mimo.
Verse 2
Opo ‘tunu wa ninu re,
Fun okan alare;
Gbogbo okan ti ongbe ngbe,
Nri omi iye mu.
Verse 3
Ninu re l’ alafia wa,
Ti Jesu fi fun wa;
Iye ainipekun si wa
N’nu re fun wa gbogbo
Verse 4
Iba le ma je ayo mi,
Lati ma ka titi;
Ki nma ri ogbon titun ko,
N’nu re lojojumo.
Verse 5
Oluwa, Oluko orun,
Mase jina si mi;
Ko mi lati fe oro Re,
Ki nri Jesu nibe.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/baba-orun-nin-oro-re/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.