EWOLE f’ Oba, ologo julo
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
EWOLE f’ Oba, ologo julo,
E korin ipa ati ife Re;
Alabo wa ni, at’ Eni Igbani,
O ngbe ‘nu ogo, eleru ni iyin.
Verse 2
E so t’ ipa Re, e so t’ ore Re:
‘Mole l’ aso Re gobi Re orun,
B’ ara ti nsan ni ‘keke, ibinu Re;
Ipa ona Re ni a ko si le mo.
Verse 3
Aiye yi pelu ekun re gbogbo,
Olorun, agbara Re l’ o da won:
O fi idi re mu ‘le, ko si le yi,
O si f’ okun se oja igbaiya re.
Verse 4
Itoju Re wa lara gbogbo won,
Ninu afefe, ninu imole;
Itoju Re wa nin ‘ odo ti o nsan,
O si wa ninu iri ati ojo.
Verse 5
Awa erupe, aw’ alailera,
‘Wo l’ a gbekele, O ki o da ni;
Anu Re ronu, o si le de opin
Eleda, Alabo, Olugbala wa.
Verse 6
‘Wo alagbara, onife julo,
B’ awon angeli ti yin O loke,
Be l’ awa eda Re niwon t’ a le se
A o ma juba Re, a o ma yin O.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.