L’ OJU ale, ‘gbat’ orun wo
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
L’ OJU ale, ‘gbat’ orun wo,
Nwon gbe abirun wodo Re:
Oniruru ni aisan won,
Sugbon nwon f’ayo lo le won
Verse 2
Jesu a de loj’ ale yi,
A sunmo, t’awa t’arun wa,
Bi a ko tile le ri O,
Sugbon a mo p’ O sunmo wa.
Verse 3
Olugbala, wo osi wa:
Omi ko san, ‘mi banuje,
Omi ko ni ife si O,
Ife elomi si tutu.
Verse 4
Omi mo pe, asan l’aiye
Beni nwon ko f’aiye sile;
Omi l’ore ti ko se ‘re
Beni nwon ko fi O s’ ore.
Verse 5
Ko s’ okan ninu wa t’ o pe,
Gbogbo wa si ni elese;
Awon t’ o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe.
Verse 6
Sugbon Jesu Olugbala,
Eni bi awa n’ Iwo se:
‘Wo ti ri ‘danwo bi awa,
‘Wo si ti mo ailera wa.
Verse 7
Agbar’ owo Re wa sile,
Oro Re si li agbara:
Gbo adura ale wa yi,
Ni anu, wo gbogbo wa san.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.