← Back to the hymnbook
Yoruba Baptist Hymns No. 510

MA sun lo, olufe; sa ma simi

Read. Sing. Share.

Verse 1

MA sun lo, olufe; sa ma simi,
F’ ori re le aiya Olugbala;
A fe o, sugbon Jesu fe o ju:-
O di owuro o!

Verse 2

Orun re dun bi orun omode,
B’ o si ji ekun ko si fun o mo,
Isimi t’o daju n’ isimi re,
O di owuro o!

Verse 3

Titi okunkun aiye y’o fi tan,
Titi ao fi ko ikore wo ‘le;
Titi oye aiye yio fi la,
O di owuro o!

Verse 4

Titi orun ajinde y’o fi yo,
Ti awon oku Jesu y’o dide;
Ti On y’o de ninu ola nla Re,
O di owuro o!

Verse 5

Titi ewa orun y’o je tire,
Ti iwo o ma tan ninu ogo,
Ti Oluwa y’o fi de o l’ ade,
O di owuro o!

Verse 6

O d’ owuro sa ni, olufe mi,
A tun fere ri ‘ra na n’ ibiti
Ipinya ati ituka ko si,
O di owuro o!

Verse 7

Tit’ ao fi pade niwaju ite,
Nin’ aso igunwa awon Tire,
Titi a o fi riran kedere,
O di owuro o!

Conversation 0 comments

Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.

Share anonymously

No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.

Where are you joining from?

Your city and country appear beside your anonymous comment after review.

Form verification is provided by Cloudflare Turnstile.

Sign in to keep track of replies

Report a lyric correction

Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.

Form verification is provided by Cloudflare Turnstile.Your details are used to respond to this submission.
Support the archive