Yoruba Baptist Hymns
MO ti mb’ese rin ti pe
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
MO ti mb’ese rin ti pe,
Pin wa n’iya, Oluwa,
Ore’parun ni tire,
Gba mi Jesu, mo segbe.
Verse 2
ko s’ anfani ti mo ri
L’ ara ati l’ okan mi,
Gbogbo re l’ o dibaje,
Jesu gba mi, mo segbe.
Verse 3
Mo r’ iye nin’ oro Re,
Ibagbe Re si wu mi,
Ese di mi mu sinsin
Gba mi Jesu, jo gba mi.
Verse 4
O ha dake ki nsegbe,
Nitori ailera m?
Oha jowo mi f’ ese?
K’ a ma ri, Jesu gba mi.
Verse 5
Iwo t’ o r’ ode,
Iyanju mi han si O,
O mo bi mo ti nja to,
O r’ omije ‘koko mi.
Verse 6
Ese fie won de mi,
Da mi, Oluwa da mi,
Iwo ni ngo sin titi,
Jesu Olugbala mi.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/mo-ti-mbese-rin-ti-pe/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.