OHUN tin dun l’ aginju
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
OHUN tin dun l’ aginju,
Ohun alore ni,
Gbo b’ o tin dun rara pe,
“E ronupiwada.”
Ohun na ko ha dun to
Ipe na ko kan o?
Kil o se, arakunrin,
Ti o ko fi mira?
Verse 2
“Ijoba ku si dede” –
Ijoba Olorun,
Awon t’ o ti fo ‘so won,
Nikan ni yio gunwa,
Ese t’ o ko fi nani
Ohun alore yi,
Ti ndun l’ eti re tantan
Pe, “Renupiwada?”
Verse 3
Abana pelu Farpar’
Le je odo mimo,
Sugbon ase ‘wenumo,
Jordan’ nikan l’ o ni;
Ju ero re s’ apakan,
Se ase Oluwa,
Wa sinu adagun yi,
We, k’ o si di mimo.
Verse 4
Kin’ iba da o duro?
Awawi kan ko si;
W’ odo, wo Jordannu re,
Ohun gbogbo setan;
O pe ti o ti njiyan,
O ha bu Emi ku?
Elese, gbo alore,
Si ronupiwada.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.